Gẹn 29:16-35

Gẹn 29:16-35 YBCV

Labani si ni ọmọbinrin meji: orukọ ẹgbọ́n a ma jẹ Lea, orukọ aburo a si ma jẹ Rakeli. Oju Lea kò li ẹwà, ṣugbọn Rakeli ṣe arẹwà, o si wù ni. Jakobu si fẹ́ Rakeli; o si wipe, Emi o sìn ọ li ọdún meje nitori Rakeli, ọmọbinrin rẹ abikẹhin. Labani si wipe, O san lati fi i fun ọ, jù ki nfi i fun ẹlomiran lọ: ba mi joko. Jakobu si sìn i li ọdún meje fun Rakeli; nwọn sì dabi ijọ́ melokan li oju rẹ̀ nitori ifẹ́ ti o fẹ́ ẹ. Jakobu si wi fun Labani pe, Fi aya mi fun mi, nitoriti ọjọ́ mi pé, ki emi ki o le wọle tọ̀ ọ. Labani si pè gbogbo awọn enia ibẹ̀ jọ, o si se àse. O si ṣe li alẹ, o mú Lea ọmọbinrin rẹ̀, o sìn i tọ̀ ọ wá; on si wọle tọ̀ ọ lọ. Labani si fi Silpa, ọmọ-ọdọ rẹ̀, fun Lea, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀. O si ṣe, li owurọ, wò o, o jẹ́ Lea: o si wi fun Labani pe, Ẽwo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? nitori Rakeli ki mo ṣe sìn ọ, njẹ ẽhatiṣe ti o fi ṣe erú si mi? Labani si wi fun u pe, A kò gbọdọ ṣe bẹ̃ ni ilẹ wa, lati sìn aburo ṣaju ẹgbọ́n. Ṣe ọ̀sẹ ti eleyi pé, awa o si fi eyi fun ọ pẹlu, nitori ìsin ti iwọ o sìn mi li ọdún meje miran si i. Jakobu si ṣe bẹ̃, o si ṣe ọ̀sẹ rẹ̀ pé: o si fi Rakeli ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya pẹlu. Labani si fi Bilha, ọmọbinrin ọdọ rẹ̀, fun Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀. O si wọle tọ̀ Rakeli pẹlu, o si fẹ́ Rakeli jù Lea lọ, o si sìn i li ọdún meje miran si i. Nigbati OLUWA si ri i pe a korira Lea, o ṣi i ni inu: ṣugbọn Rakeli yàgan. Lea si loyun, o si bí ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Reubeni: nitori ti o wipe, OLUWA wò ìya mi nitõtọ: njẹ nitorina, ọkọ mi yio fẹ́ mi. O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Nitori ti OLUWA ti gbọ́ pe a korira mi, nitorina li o ṣe fun mi li ọmọ yi pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Simeoni. O si tun loyun, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Njẹ nigbayi li ọkọ mi yio faramọ́ mi, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹta fun u: nitorina li o ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Lefi. O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan: o si wipe, Nigbayi li emi o yìn OLUWA: nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Judah; o si dẹkun bíbi.