Gẹn 26

26
Isaaki Gbé ní Gerari
1ÌYAN kan si mu ni ilẹ na, lẹhin ìyan ti o tetekọ mu li ọjọ́ Abrahamu. Isaaki si tọ̀ Abimeleki, ọba awọn ara Filistia lọ, si Gerari.
2OLUWA si farahàn a, o si wipe, Máṣe sọkalẹ lọ si Egipti; joko ni ilẹ ti emi o wi fun ọ.
3Mã ṣe atipo ni ilẹ yi, emi o si pẹlu rẹ, emi o si bukún u fun ọ; nitori iwọ ati irú-ọmọ rẹ, li emi o fi gbogbo ilẹ wọnyi fun, emi o si mu ara ti mo bú fun Abrahamu, baba rẹ, ṣẹ.
4Emi o si mu irú-ọmọ rẹ bisi i bi irawọ oju-ọrun, emi o si fi gbogbo ilẹ wọnyi fun irú-ọmọ rẹ; ati nipasẹ irú-ọmọ rẹ li a o bukún gbogbo orilẹ-ède aiye;
5Nitoriti Abrahamu gbà ohùn mi gbọ́, o si pa ìlọ mi, aṣẹ mi, ìlana mi, ati ofin mi mọ́.
6Isaaki si joko ni Gerari.
7Awọn ọkunrin ibẹ̀ na bi i lẽre niti aya rẹ̀: o si wipe, Arabinrin mi ni: nitoriti o bẹ̀ru ati wipe, Aya mi ni; o ni, ki awọn ọkunrin ibẹ̀ na ki o má ba pa mi nitori Rebeka; nitoriti on li ẹwà lati wò.
8O si ṣe nigbati o joko nibẹ̀ pẹ titi, ni Abimeleki, ọba awọn ara Filistia, wò ode li ojuferese, o si ri, si kiyesi i, Isaaki mba Rebeka aya rẹ̀ wẹ́.
9Abimeleki si pè Isaaki, o si wipe, Kiyesi i, nitõtọ aya rẹ ni iṣe: iwọ ha ti ṣe wipe, Arabinrin mi ni? Isaaki si wi fun u pe, Nitoriti mo wipe, ki emi ki o má ba kú nitori rẹ̀.
10Abimeleki si wipe, Kili eyiti iwọ ṣe si wa yi? Bí ọkan ninu awọn enia bá lọ bá aya rẹ ṣe iṣekuṣe nkọ? iwọ iba si mu ẹ̀ṣẹ wá si ori wa.
11Abimeleki si kìlọ fun gbogbo awọn enia rẹ̀ wipe, Ẹnikẹni ti o ba tọ́ ọkunrin yi tabi aya rẹ̀, kikú ni yio kú.
12Nigbana ni Isaaki funrugbìn ni ilẹ na, o si ri ọrọrún mu li ọdún na; OLUWA si busi i fun u:
13Ọkunrin na si di pupọ̀, o si nlọ si iwaju, o si npọ̀ si i titi o fi di enia nla gidigidi.
14Nitori ti o ni agbo-agutan, ati ini agbo-ẹran nla ati ọ̀pọlọpọ ọmọ-ọdọ: awọn ara Filistia si ṣe ilara rẹ̀.
15Nitori gbogbo kanga ti awọn ọmọ-ọdọ baba rẹ̀ ti wà li ọjọ́ Abrahamu, baba rẹ̀, awọn ara Filistia dí wọn, nwọn si fi erupẹ dí wọn.
16Abimeleki si wi fun Isaaki pe, Lọ kuro lọdọ wa; nitori ti iwọ lagbara pupọ̀ ju wa lọ.
17Isaaki si ṣí kuro nibẹ̀, o si pa agọ́ rẹ̀ ni afonifoji Gerari, o si joko nibẹ̀.
18Isaaki si tun wà kanga omi, ti nwọn ti wà li ọjọ́ Abrahamu, baba rẹ̀; nitori ti awọn ara Filistia ti dí wọn lẹhin ikú Abrahamu: o si pè orukọ wọn gẹgẹ bi orukọ ti baba rẹ̀ sọ wọn.
19Awọn ọmọ-ọdọ Isaaki si wàlẹ li afonifoji nì, nwọn si kàn kanga isun omi nibẹ̀.
20Awọn darandaran Gerari si mba awọn darandaran Isaaki jà, wipe, Ti wa li omi na: o si sọ orukọ kanga na ni Eseki; nitori ti nwọn bá a jà.
21Nwọn si tun wà kanga miran, nwọn si tun jà nitori eyi na pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Sitna.
22O si ṣí kuro nibẹ̀, o si wà kanga miran: nwọn kò si jà nitori rẹ̀: o si pè orukọ rẹ̀ ni Rehoboti; o si wipe, Njẹ nigbayi li OLUWA tó fi àye fun wa, awa o si ma bisi i ni ilẹ yi.
23O si goke lati ibẹ̀ lọ si Beer-ṣeba.
24OLUWA si farahàn a li oru ọjọ́ na, o si wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ: máṣe bẹ̀ru, nitori ti emi wà pẹlu rẹ, emi o si busi i fun ọ, emi o si mu irú-ọmọ rẹ rẹ̀, nitori Abrahamu ọmọ-ọdọ mi.
25O si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si kepè orukọ OLUWA, o si pa agọ́ rẹ̀ nibẹ̀: awọn ọmọ-ọdọ Isaaki si wà kanga kan nibẹ̀.
Abimeleki ati Isaaki Dá Majẹmu
26Nigbana li Abimeleki tọ̀ ọ lati Gerari lọ, ati Ahusati, ọkan ninu awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ati Fikoli, olori ogun rẹ̀.
27Isaaki si bi wọn pe, Nitori kili ẹnyin ṣe tọ̀ mi wá, ẹnyin sa korira mi, ẹnyin si ti lé mi kuro lọdọ nyin?
28Nwọn si wipe, Awa ri i nitõtọ pe, OLUWA wà pẹlu rẹ: awa si wipe, Njẹ nisisiyi jẹ ki ibura ki o wà lãrin wa, ani lãrin tawa tirẹ, ki awa ki o si ba iwọ dá majẹmu;
29Pe iwọ ki yio ṣe wa ni ibi, bi awa kò si ti fọwọkàn ọ, ati bi awa kò si ti ṣe ọ ni nkan bikoṣe rere, ti awa si rán ọ jade li alafia: nisisiyi ẹni-ibukún OLUWA ni iwọ.
30O si sè àse fun wọn, nwọn si jẹ, nwọn si mu.
31Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn si bura fun ara wọn: Isaaki si rán wọn pada lọ, nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀ li alafia.
32O si ṣe li ọjọ́ kanna li awọn ọmọ-ọdọ Isaaki wá, nwọn si rò fun u niti kanga ti nwọn wà, nwọn si wi fun u pe, Awa kàn omi.
33O sọ orukọ rẹ̀ ni Ṣeba: nitorina li orukọ ilu na ṣe njẹ Beer-ṣeba titi di oni.
Àwọn Obinrin Àjèjì Tí Esau Fẹ́
34Esau si di ẹni ogoji ọdún nigbati o mu Juditi li aya, ọmọbinrin Beeri, ara Hitti, ati Baṣemati, ọmọbinrin Eloni, ara Hitti:
35Ohun ti o ṣe ibinujẹ fun Isaaki ati fun Rebeka.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Gẹn 26: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa