Gẹn 25:27-34

Gẹn 25:27-34 YBCV

Awọn ọmọdekunrin na si dàgba: Esau si ṣe ọlọgbọ́n ọdẹ, ara oko; Jakobu si ṣe ọbọrọ́ enia, a ma gbé inu agọ́. Isaaki si fẹ́ Esau, nitori ti o njẹ ninu ẹran-ọdẹ rẹ̀: ṣugbọn Rebeka fẹ́ Jakobu. Jakobu si pa ìpẹtẹ: Esau si ti inu igbẹ́ dé, o si rẹ̀ ẹ: Esau si wi fun Jakobu pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ìpẹtẹ rẹ pupa nì bọ́ mi; nitori ti o rẹ̀ mi: nitori na li a ṣe npè orukọ rẹ̀ ni Edomu. Jakobu si wipe, Tà ogún-ibí rẹ fun mi loni. Esau si wipe, Sa wò o na, emi ni nkú lọ yi: ore kini ogún-ibí yi yio si ṣe fun mi? Jakobu si wipe, Bura fun mi loni; o si bura fun u: o si tà ogún-ibí rẹ̀ fun Jakobu. Nigbana ni Jakobu fi àkara ati ìpẹtẹ lentile fun Esau; o si jẹ, o si mu, o si dide, o si ba tirẹ̀ lọ: bayi ni Esau gàn ogún-ibí rẹ̀.