Gẹn 25:19-21

Gẹn 25:19-21 YBCV

Iwọnyi si ni iran Isaaki, ọmọ Abrahamu: Abrahamu bí Isaaki: Isaaki si jẹ ẹni ogoji ọdún, nigbati o mu Rebeka, ọmọbinrin Betueli, ara Siria ti Padan-aramu, arabinrin Labani ara Siria, li aya. Isaaki si bẹ̀ OLUWA fun aya rẹ̀, nitoriti o yàgan: OLUWA si gbà ẹ̀bẹ rẹ̀, Rebeka, aya rẹ̀, si loyun.