Gẹn 23:3-6

Gẹn 23:3-6 YBCV

Abrahamu si dide kuro niwaju okú rẹ̀, o si sọ fun awọn ọmọ Heti, wipe, Alejò ati atipo li emi iṣe lọdọ nyin: ẹ fun mi ni ilẹ-isinku lãrin nyin, ki emi ki o le sin okú mi kuro ni iwaju mi. Awọn ọmọ Heti si dá Abrahamu lohùn, nwọn si wi fun u pe, Oluwa mi, gbọ́ ti wa: alagbara ọmọ-alade ni iwọ lãrin wa: ninu ãyò bojì wa ni ki o sin okú rẹ; kò sí ẹnikẹni ninu wa ti yio fi ibojì rẹ̀ dù ọ, ki iwọ ki o má sin okú rẹ.