Gẹn 22:15-18

Gẹn 22:15-18 YBCV

Angeli OLUWA nì si kọ si Abrahamu lati ọrun wá lẹrinkeji, O si wipe, Emi tikalami ni mo fi bura, li OLUWA wi, nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo: Pe ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bíbisi emi o mu irú-ọmọ rẹ bísi i bi irawọ oju-ọrun, ati bi iyanrin eti okun; irú-ọmọ rẹ ni yio si ni ẹnubode awọn ọta wọn; Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède aiye: nitori ti iwọ ti gbà ohùn mi gbọ́.