Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o mu àkara ati ìgo omi kan, o fi fun Hagari, o gbé e lé e li ejika, ati ọmọ na, o si lé e jade: on si lọ, o nrìn kakiri ni ijù Beer-ṣeba. Omi na si tán ninu ìgo, o si sọ̀ ọmọ na si abẹ ìgboro kan. O si lọ, o joko kọju si i, li ọ̀na jijìn rére, o tó bi itafasi kan: nitori ti o wipe, Ki emi má ri ikú ọmọ na. O si joko kọju si i, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o nsọkun. Ọlọrun si gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na: angeli Ọlọrun si pè Hagari lati ọrun wá, o bi i pe, Kili o ṣe ọ, Hagari? máṣe bẹ̀ru; nitori ti Ọlọrun ti gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na nibiti o gbé wà. Dide, gbé ọmọdekunrin na, ki o si dì i mu; nitori ti emi o sọ ọ di orilẹ-ède nla.
Kà Gẹn 21
Feti si Gẹn 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 21:14-18
5 Awọn ọjọ
Gbigbe irin ajo lọ si ohun ti a npe ni igbagbọ ti Bibeli A wo ìgbésí ayé Ábúráhámù, baba ńlá ìgbàgbọ́ nínú Bíbélì, àti díẹ̀ lára àwọn ìjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́ run, àwọn ìtọ́ ni wo ló ní láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́ run tí ó sì ṣègbọràn sí ohun tí Ọlọ́ run béèrè lọ́ wọ́ rẹ̀? Ti kii ba ṣe bẹ, awọn abajade odi wa fun iyapa rẹ?
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò