Gẹn 2:8-14

Gẹn 2:8-14 YBCV

OLUWA Ọlọrun si gbìn ọgbà kan niha ìla-õrùn ni Edeni; nibẹ̀ li o si fi ọkunrin na ti o ti mọ si. Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun mu onirũru igi hù jade wá, ti o dara ni wiwò, ti o si dara fun onjẹ; ìgi ìye pẹlu lãrin ọgbà na, ati igi ìmọ rere ati buburu. Odò kan si ti Edeni ṣàn wá lati rin ọgbà na; lati ibẹ̀ li o gbé yà, o si di ipa ori mẹrin. Orukọ ekini ni Pisoni: on li eyiti o yi gbogbo ilẹ Hafila ká, nibiti wurà wà; Wurà ilẹ na si dara: nibẹ ni bedeliumu (ojia) wà ati okuta oniki. Orukọ odò keji si ni Gihoni: on na li eyiti o yi gbogbo ilẹ Kuṣi ká. Ati orukọ odò kẹta ni Hiddekeli: on li eyiti nṣàn lọ si ìha ìla-õrùn Assiria. Ati odò kẹrin ni Euferate.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Gẹn 2:8-14