Abrahamu si sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Iwọ o ha run olododo pẹlu enia buburu?
Bọya ãdọta olododo yio wà ninu ilu na: iwọ o ha run u, iwọ ki yio ha dá ibẹ̀ na si nitori ãdọta olododo ti o wà ninu rẹ̀?
O ha dára, ti iwọ o fi ṣe bi irú eyi, lati run olododo pẹlu enia buburu; ti awọn olododo yio fi dabi awọn enia buburu, o ha dára: Onidajọ gbogbo aiye ki yio ha ṣe eyi ti o tọ́?
OLUWA si wipe, Bi mo ba ri ãdọta olododo ninu ilu Sodomu, njẹ emi o dá gbogbo ibẹ̀ si nitori wọn.
Abrahamu si dahùn o si wipe, Wò o nisisiyi, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ, emi ẹniti iṣe erupẹ ati ẽru.
Bọya marun a dín ninu ãdọta olododo na: iwọ o ha run gbogbo ilu na nitori marun? On si wipe, Bi mo ba ri marunlelogoji nibẹ̀, emi ki yio run u.
O si tun sọ fun u ẹ̀wẹ, o ni, Bọya, a o ri ogoji nibẹ̀, On si wipe, Emi ki o run u nitori ogoji.
O si tun wipe, Jọ̃, ki inu ki o máṣe bi OLUWA, emi o si ma wi: bọya a o ri ọgbọ̀n nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u bi mo ba ri ọgbọ̀n nibẹ̀.
O si wipe, Wò o na, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ: bọya a o ri ogun nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u nitori ogun.
O si wipe, Jọ̃, ki inu ki o máṣe bi OLUWA, ẹ̃kanṣoṣo yi li emi o si wi mọ. Bọya a o ri mẹwa nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u nitori mẹwa.
OLUWA si ba tirẹ̀ lọ, lojukanna bi o ti ba Abrahamu sọ̀rọ tan; Abrahamu si pada lọ si ibujoko rẹ̀.