Gẹn 17:1-4

Gẹn 17:1-4 YBCV

NIGBATI Abramu si di ẹni ọkandilọgọrun ọdún, OLUWA farahàn Abramu, o si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare; mã rìn niwaju mi, ki iwọ ki o si pé. Emi o si ba ọ dá majẹmu mi, emi o si sọ ọ di pupọ̀ gidigidi. Abramu si dojubolẹ; Ọlọrun si ba a sọ̀rọ pe, Bi o ṣe ti emi ni, kiyesi i, majẹmu mi wà pẹlu rẹ, iwọ o si ṣe baba orilẹ-ède pupọ̀.