Angeli OLUWA si ri i li ẹba isun omi ni ijù, li ẹba isun omi li ọ̀na Ṣuri. O si wipe, Hagari ọmọbinrin ọdọ Sarai, nibo ni iwọ ti mbọ̀? nibo ni iwọ si nrè? O si wipe, emi sá kuro niwaju Sarai oluwa mi. Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Pada, lọ si ọdọ oluwa rẹ, ki o si tẹriba fun u. Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Ni bíbi emi o mu iru-ọmọ rẹ bísi i, a ki yio si le kà wọn fun ọ̀pọlọpọ. Angeli OLUWA na si wi fun u pe, kiyesi i iwọ loyun, iwọ o si bí ọmọkunrin, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Iṣmaeli; nitoriti OLUWA ti gbọ́ ohùn arò rẹ. Jagidijagan enia ni yio si ṣe; ọwọ́ rẹ̀ yio wà lara enia gbogbo, ọwọ́ enia gbogbo yio si wà lara rẹ̀: on o si ma gbé iwaju gbogbo awọn arakunrin rẹ̀. O si pè orukọ OLUWA ti o ba a sọ̀rọ ni, Iwọ Ọlọrun ti o ri mi: nitori ti o wipe, Emi ha wá ẹniti o ri mi kiri nihin? Nitori na li a ṣe npè kanga na ni Beer-lahai-roi: kiyesi i, o wà li agbedemeji Kadeṣi on Beredi. Hagari si bí ọmọkunrin kan fun Abramu: Abramu si pè orukọ ọmọ ti Hagari bí ni Iṣmaeli. Abramu si jẹ ẹni ẹrindilãdọrun ọdún, nigbati Hagari bí Iṣmaeli fun Abramu.
Kà Gẹn 16
Feti si Gẹn 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 16:7-16
5 Awọn ọjọ
Gbigbe irin ajo lọ si ohun ti a npe ni igbagbọ ti Bibeli A wo ìgbésí ayé Ábúráhámù, baba ńlá ìgbàgbọ́ nínú Bíbélì, àti díẹ̀ lára àwọn ìjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́ run, àwọn ìtọ́ ni wo ló ní láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́ run tí ó sì ṣègbọràn sí ohun tí Ọlọ́ run béèrè lọ́ wọ́ rẹ̀? Ti kii ba ṣe bẹ, awọn abajade odi wa fun iyapa rẹ?
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò