Ọba Sodomu si jade lọ ipade rẹ̀ li àbọ iṣẹgun Kedorlaomeri ati awọn ọba ti o pẹlu rẹ̀, li afonifoji Ṣafe, ti iṣe Afonifoji Ọba. Melkisedeki ọba Salemu si mu onjẹ ati ọti waini jade wá: on a si ma ṣe alufa Ọlọrun Ọga-ogo. O si súre fun u, o si wipe, Ibukun ni fun Abramu, ti Ọlọrun ọga-ogo, ẹniti o ni ọrun on aiye. Olubukun si li Ọlọrun ọga-ogo ti o fi awọn ọta rẹ le ọ lọwọ. On si dá idamẹwa ohun gbogbo fun u. Ọba Sodomu si wi fun Abramu pe, Dá awọn enia fun mi, ki o si mu ẹrù fun ara rẹ. Abramu si wi fun ọba Sodomu pe, Mo ti gbé ọwọ́ mi soke si OLUWA, Ọlọrun ọga-ogo, ti o ni ọrun on aiye, Pe, emi ki yio mu lati fọnran owu titi dé okùn bàta, ati pe, emi kì yio mu ohun kan ti iṣe tirẹ, ki iwọ ki o má ba wipe, Mo sọ Abramu di ọlọrọ̀: Bikoṣe kìki eyiti awọn ọdọmọkunrin ti jẹ, ati ipín ti awọn ọkunrin ti o ba mi lọ; Aneri, Eṣkoli, ati Mamre; jẹ ki nwọn ki o mu ipín ti wọn.
Kà Gẹn 14
Feti si Gẹn 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 14:17-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò