O si nṣikẹ Abramu gidigidi nitori rẹ̀: on si li agutan, ati akọ-malu, ati akọ-kẹtẹkẹtẹ, ati iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, abo-kẹtẹkẹtẹ, ati ibakasiẹ. OLUWA si fi iyọnu nla yọ Farao ati awọn ara ile rẹ̀ li ẹnu, nitori Sarai aya Abramu. Farao si pè Abramu, o wipe, ewo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? ẽṣe ti iwọ kò fi wi fun mi pe, aya rẹ ni iṣe? Ẽṣe ti iwọ fi wipe, arabinrin mi ni iṣe? bẹ̃li emi iba fẹ ẹ li aya mi si: njẹ nisisiyi wò aya rẹ, mu u, ki o si ma ba tirẹ lọ. Farao si paṣẹ fun awọn ọkunrin rẹ̀ nitori Abramu: nwọn si sìn i jade lọ, ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni.
Kà Gẹn 12
Feti si Gẹn 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 12:16-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò