Gẹn 12:11-13

Gẹn 12:11-13 YBCV

O si ṣe, nigbati o kù si dẹ̀dẹ lati wọ̀ Egipti, o wi fun Sarai aya rẹ̀ pe, Kiyesi i nisisiyi, emi mọ̀ pe arẹwà obinrin lati wò ni iwọ: Nitorina yio si ṣe, nigbati awọn ara Egipti yio ri ọ, nwọn o wipe, aya rẹ̀ li eyi: nwọn o si pa mi, ṣugbọn nwọn o dá ọ si. Mo bẹ̀ ọ, wipe, arabinrin mi ni iwọ iṣe: ki o le irọ̀ mi lọrùn nitori rẹ; ọkàn mi yio si yè nitori rẹ.