Gẹn 11:27-32

Gẹn 11:27-32 YBCV

Iran Tera si li eyi: Tera bi Abramu, Nahori, ati Harani; Harani si bí Loti. Harani si kú ṣaju Tera baba rẹ̀, ni ilẹ ibi rẹ̀, ni Uri ti Kaldea. Ati Abramu ati Nahor si fẹ aya fun ara wọn: orukọ aya Abramu ni Sarai; ati orukọ aya Nahori ni Milka, ọmọbinrin Harani, baba Milka, ati baba Iska. Ṣugbọn Sarai yàgan; kò li ọmọ. Tera si mu Abramu ọmọ rẹ̀, ati Loti, ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ati Sarai aya ọmọ rẹ̀, aya Abramu ọmọ rẹ̀; nwọn si ba wọn jade kuro ni Uri ti Kaldea, lati lọ si ilẹ Kenaani; nwọn si wá titi de Harani, nwọn si joko sibẹ̀. Ọjọ́ Tera si jẹ igba ọdún o le marun: Tera si kú ni Harani.