Ọlọrun si wipe, Ki omi ki o kún fun ọ̀pọlọpọ ẹdá alãye ti nrakò, ati ki ẹiyẹ ki o ma fò loke ilẹ li oju-ofurufu ọrun. Ọlọrun si dá erinmi nlanla ati ẹdá alãye gbogbo ti nrakò, ti omi kún fun li ọ̀pọlọpọ ni irú wọn, ati ẹiyẹ abiyẹ ni irú rẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. Ọlọrun si súre fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ẹ si mã rẹ̀, ki ẹ kún inu omi li okun, ki ẹiyẹ ki o si ma rẹ̀ ni ilẹ. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ karun. Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o mu ẹdá alãye ni irú rẹ̀ jade wá, ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹranko ilẹ ni irú rẹ̀: o si ri bẹ̃. Ọlọrun si dá ẹranko ilẹ ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara.
Kà Gẹn 1
Feti si Gẹn 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 1:20-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò