Gẹn 1:20-23

Gẹn 1:20-23 YBCV

Ọlọrun si wipe, Ki omi ki o kún fun ọ̀pọlọpọ ẹdá alãye ti nrakò, ati ki ẹiyẹ ki o ma fò loke ilẹ li oju-ofurufu ọrun. Ọlọrun si dá erinmi nlanla ati ẹdá alãye gbogbo ti nrakò, ti omi kún fun li ọ̀pọlọpọ ni irú wọn, ati ẹiyẹ abiyẹ ni irú rẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. Ọlọrun si súre fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ẹ si mã rẹ̀, ki ẹ kún inu omi li okun, ki ẹiyẹ ki o si ma rẹ̀ ni ilẹ. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ karun.