Gẹn 1:18-20

Gẹn 1:18-20 YBCV

Ati lati ṣe akoso ọsán ati akoso oru, ati lati pàla imọlẹ on òkunkun: Ọlọrun si ri pe o dara. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹrin. Ọlọrun si wipe, Ki omi ki o kún fun ọ̀pọlọpọ ẹdá alãye ti nrakò, ati ki ẹiyẹ ki o ma fò loke ilẹ li oju-ofurufu ọrun.