Gẹn 1:11-12

Gẹn 1:11-12 YBCV

Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o hù oko, eweko ti yio ma so eso, ati igi eleso ti yio ma so eso ni irú tirẹ̀, ti o ni irugbin ninu lori ilẹ: o si ri bẹ̃. Ilẹ si sú koriko jade, eweko ti nso eso ni irú tirẹ̀, ati igi ti nso eso, ti o ni irugbin ninu ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara.