Gẹn 1:1-3

Gẹn 1:1-3 YBCV

Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye. Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi. Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà.