Nitori a ti kọ ọ pe, Mã yọ̀, iwọ àgan ti kò bímọ: bú si ayọ̀ ki o si kigbe soke, iwọ ti kò rọbi rí; nitori awọn ọmọ ẹni alahoro pọ̀ jù ti abilekọ lọ. Njẹ ará, ọmọ ileri li awa gẹgẹ bi Isaaki. Ṣugbọn bi eyiti a bí nipa ti ara ti ṣe inunibini nigbana si eyiti a bí nipa ti Ẹmi, bẹ̃ si ni nisisiyi. Ṣugbọn iwe-mimọ́ ha ti wi? Lé ẹrú-binrin na jade ati ọmọ rẹ̀: nitori ọmọ ẹrú-binrin kì yio ba ọmọ omnira-obinrin jogun pọ̀. Nitorina, ará, awa kì iṣe ọmọ ẹrú-binrin, bikoṣe ti omnira-obinrin.
Kà Gal 4
Feti si Gal 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gal 4:27-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò