Gal 4:12-20

Gal 4:12-20 YBCV

Ará, mo bẹ̀ nyin, ẹ dà bi emi; nitori emi dà bi ẹnyin: ẹnyin kò ṣe mi ni ibi kan. Ṣugbọn ẹnyin mọ̀ pe ailera ara li o jẹ ki nwasu ihinrere fun nyin li akọṣe. Eyiti o si jẹ idanwo fun nyin li ara mi li ẹ kò kẹgàn, bẹni ẹ kò si kọ̀; ṣugbọn ẹnyin gbà mi bi angẹli Ọlọrun, ani bi Kristi Jesu. Njẹ ayọ nyin igbana ha da? nitori mo gbà ẹ̀ri nyin jẹ pe, iba ṣe iṣe, ẹ ba yọ oju nyin jade, ẹ ba si fi wọn fun mi. Njẹ mo ha di ọta nyin nitori mo sọ otitọ fun nyin bi? Nwọn nfi itara wá nyin, ṣugbọn ki iṣe fun rere; nwọn nfẹ já nyin kuro, ki ẹnyin ki o le mã wá wọn. Ṣugbọn o dara lati mã fi itara wá ni fun rere nigbagbogbo, kì si iṣe nigbati mo wà pẹlu nyin nikan. Ẹnyin ọmọ mi kekeke, ẹnyin ti mo tún nrọbi titi a o fi ṣe ẹda Kristi ninu nyin. Iba wù mi lati wà lọdọ nyin nisisiyi, ki emi ki o si yi ohùn mi pada nitoripe mo dãmu nitori nyin.