Njẹ nisisiyi enia ni emi nyi lọkàn pada tabi Ọlọrun? tabi enia ni emi nfẹ lati wù? nitoripe bi emi ba si nwù enia, emi kì yio le ṣe iranṣẹ Kristi. Ṣugbọn, ará, mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe ihinrere ti mo ti wasu kì iṣe nipa ti enia. Nitori kì iṣe lọwọ enia ni mo ti gbà a, bẹ̃li a kò fi kọ́ mi, ṣugbọn nipa ifihan Jesu Kristi. Nitori ẹnyin ti gburó ìwa-aiye mi nigba atijọ ninu ìsin awọn Ju, bi mo ti ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun rekọja ãlà, ti mo si bà a jẹ: Mo si ta ọpọlọpọ awọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ ninu isin awọn Ju larin awọn ara ilu mi, mo si ni itara lọpọlọpọ si ofin atọwọdọwọ awọn baba mi. Ṣugbọn nigbati o wù Ọlọrun, ẹniti o yà mi sọtọ lati inu iya mi wá, ti o si pè mi nipa ore-ọfẹ rẹ̀, Lati fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, ki emi le mã wasu rẹ̀ larin awọn Keferi; lojukanna emi kò bá ara ati ẹ̀jẹ gbìmọ pọ̀: Bẹ̃ni emi kò gòke lọ si Jerusalemu tọ̀ awọn ti iṣe Aposteli ṣaju mi; ṣugbọn mo lọ si Arabia, mo si tún pada wá si Damasku. Lẹhin ọdún mẹta, nigbana ni mo gòke lọ si Jerusalemu lati lọ kí Peteru, mo si gbé ọdọ rẹ̀ ni ijọ mẹdogun. Ṣugbọn emi kò ri ẹlomiran ninu awọn Aposteli miran, bikoṣe Jakọbu arakunrin Oluwa. Nkan ti emi nkọ̀we si nyin yi, kiyesi i, niwaju Ọlọrun emi kò ṣeke. Lẹhin na mo si wá si ẹkùn Siria ati ti Kilikia; Mo sì jẹ ẹniti a kò mọ̀ li oju fun awọn ijọ ti o wà ninu Kristi ni Judea: Ṣugbọn kìki nwọn ti gbọ́ pe, Ẹniti o ti nṣe inunibini si wa rí, si nwasu igbagbọ́ na nisisiyi, ti o ti mbajẹ nigbakan rí. Nwọn si nyin Ọlọrun logo nitori mi.
Kà Gal 1
Feti si Gal 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gal 1:10-24
7 Days
We’re all chasing something. Usually something just out of reach—a better job, a more comfortable home, a perfect family, the approval of others. But isn’t this tiring? Is there a better way? Find out in this new Life.Church Bible Plan, accompanying Pastor Craig Groeschel’s message series, Chasing Carrots.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò