Ati iwọ, Esra, gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun rẹ ti o wà li ọwọ rẹ, yan awọn oloyè ati onidajọ, ti nwọn o ma da ẹjọ fun gbogbo awọn enia ti o wà li oke-odò, gbogbo iru awọn ti o mọ̀ ofin Ọlọrun rẹ, ki ẹnyin ki o si ma kọ́ awọn ti kò mọ̀ wọn. Ẹnikẹni ti kì o si ṣe ofin Ọlọrun rẹ, ati ofin ọba, ki a mu idajọ ṣe si i lara li aijafara, bi o ṣe si ikú ni, tabi lilé si oko, tabi kiko li ẹrù, tabi si sisọ sinu tubu. Olubukun li Oluwa Ọlọrun awọn baba wa, ti o fi nkan bi iru eyi si ọkàn ọba, lati ṣe ogo si ile Oluwa ti o wà ni Jerusalemu: Ti o si nàwọ anu si mi niwaju ọba ati awọn ìgbimọ rẹ̀, ati niwaju gbogbo awọn alagbara ijoye ọba: mo si ri iranlọwọ gbà gẹgẹ bi ọwọ Oluwa Ọlọrun mi ti o wà lara mi, mo si ko awọn olori awọn enia jọ lati inu Israeli jade, lati ba mi goke lọ.
Kà Esr 7
Feti si Esr 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Esr 7:25-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò