NIGBANA ni Dariusi ọba paṣẹ, a si wá inu ile ti a ko iwe jọ si, nibiti a to iṣura jọ si ni Babiloni. A si ri iwe kan ni Ekbatana, ninu ilu olodi ti o wà ni igberiko Medea, ati ninu rẹ̀ ni iwe-iranti kan wà ti a kọ bayi: Li ọdun ikini Kirusi ọba, Kirusi ọba na paṣẹ nipasẹ ile Ọlọrun ni Jerusalemu pe, Ki a kọ́ ile na, ibi ti nwọn o ma ru ẹbọ, ki a si fi ipilẹ rẹ̀ lelẹ ṣinṣin, ki giga rẹ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀, ọgọta igbọnwọ.
Kà Esr 6
Feti si Esr 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Esr 6:1-3
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò