Esr 1:1-3

Esr 1:1-3 YBCV

LI ọdun ekini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ OLUWA lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, OLUWA rú ẹmi Kirusi, ọba Persia soke, ti o mu ki a kede yi gbogbo ijọba rẹ̀ ka, a si kọwe rẹ̀ pẹlu wipe, Bayi ni Kirusi ọba Persia wi pe, OLUWA, Ọlọrun ọrun, ti fi gbogbo ijọba aiye fun mi; o si ti pa a li aṣẹ lati kọ ile fun on ni Jerusalemu ti o wà ni Juda. Tani ninu nyin ninu gbogbo enia rẹ̀? ki Ọlọrun rẹ̀ ki o wà pẹlu rẹ̀, ki o si goke lọ si Jerusalemu, ti o wà ni Juda, ki o si kọ ile OLUWA Ọlọrun Israeli, on li Ọlọrun, ti o wà ni Jerusalemu.