Esek 48:1-9
Esek 48:1-9 YBCV
WỌNYI si ni orukọ awọn ẹ̀ya na. Lati opin ariwa titi de ọwọ́ ọ̀na Hetlonu, bi a ba nlọ si Hamati, Hasaenani, leti Damasku niha ariwa, de ọwọ́ Hamati; wọnyi sa ni ihà rẹ̀ ni ila-õrun ati iwọ-õrun; ipin kan fun Dani. Ati ni àgbegbe Dani, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Aṣeri. Ati ni àgbegbe Aṣeri, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Naftali. Ati ni àgbegbe Naftali, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Manasse. Ati ni àgbegbe Manasse, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Efraimu. Ati ni àgbegbe Efraimu, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Reubeni. Ati ni àgbegbe Reubeni, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Juda. Ati ni àgbegbe Juda, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun ni yio jẹ ọrẹ ti ẹnyin o ta, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ije ni ibú, ati ni gigùn, bi ọkan ninu awọn ipin iyokù, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun: ibi mimọ́ yio si wà lãrin rẹ̀. Ọrẹ ti ẹnyin o si ta fun Oluwa yio jẹ ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbã-marun ni ibú.

