Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nisisiyi li emi o mu igbèkun Jakobu padà bọ̀, emi o si ṣãnu fun gbogbo ile Israeli, emi o si jowu nitori orukọ mi mimọ́: Nwọn o si rù itiju wọn, ati gbogbo ọ̀tẹ wọn ti nwọn ti ṣe si mi, nigbati nwọn ngbe laibẹ̀ru ni ilẹ wọn, ti ẹnikẹni kò si dẹ̀ruba wọn. Nigbati emi ti mu wọn bọ̀ lati ọdọ orilẹ-ède, ti mo si ko wọn jọ lati ilẹ awọn ọta wọn wá, ti a si yà mi si mimọ́ ninu wọn niwaju orilẹ-ède pupọ. Nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun wọn, nipa kikó ti mo mu ki a kó wọn lọ si igbekun lãrin awọn keferi: ṣugbọn mo ti ṣà wọn jọ si ilẹ wọn, emi kò si fi ẹnikẹni wọn silẹ nibẹ mọ. Emi kì yio si fi oju mi pamọ kuro lọdọ wọn mọ: nitori emi ti tú ẹmi mi sori ile Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Kà Esek 39
Feti si Esek 39
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Esek 39:25-29
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò