Esek 37:12-14

Esek 37:12-14 YBCV

Nitorina sọtẹlẹ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, ẹnyin enia mi, emi o ṣi ibojì nyin, emi o si mu ki ẹ dide kuro ninu ibojì nyin, emi o si mu nyin wá si ilẹ Israeli. Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi bá ti ṣí ibojì nyin, ẹnyin enia mi, ti emi bá si mu nyin dide kuro ninu ibojì nyin. Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, ẹnyin o si yè, emi o si mu nyin joko ni ilẹ ti nyin: nigbana li ẹnyin o mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti sọ ọ, ti o si ti ṣe e, li Oluwa wi.