Esek 34:11-12

Esek 34:11-12 YBCV

Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi, ani emi, o bere awọn agutan mi, emi o si wá wọn ri. Gẹgẹ bi oluṣọ́ agutan iti iwá ọwọ́-ẹran rẹ̀ ri, li ọjọ ti o wà lãrin awọn agutan rẹ̀ ti o fọnka, bẹ̃li emi o wá agutan mi ri, emi o si gbà wọn nibi gbogbo ti wọn ti fọnka si, li ọjọ kũkũ ati okùnkun biribiri.