Iwọ ti wà ni Edeni ọgbà Ọlọrun; oniruru okuta iyebiye ni ibora rẹ, sardiu, topasi, ati diamondi, berili, oniki, ati jasperi, safire, emeraldi, ati karbunkili, ati wura: iṣẹ ìlu rẹ ati ti fère rẹ li a pèse ninu rẹ li ọjọ ti a dá ọ. Iwọ ni kerubu ti a nà ti o si bò; emi si ti gbe ọ kalẹ: iwọ wà lori oke mimọ́ Ọlọrun; iwọ ti rìn soke rìn sodò lãrin okuta iná. Iwọ pé li ọnà rẹ lati ọjọ ti a ti dá ọ, titi a fi ri aiṣedẽde ninu rẹ. Nitori ọ̀pọlọpọ òwo rẹ, nwọn ti fi iwà-ipa kún ãrin rẹ, iwọ si ti ṣẹ̀: nitorina li emi o ṣe sọ ọ nù bi ohun ailọ̀wọ kuro li oke Ọlọrun: emi o si pa ọ run, iwọ kerubu ti o bò, kuro lãrin okuta iná. Ọkàn rẹ gbe soke nitori ẹwà rẹ, o ti bà ọgbọ́n rẹ jẹ nitori dídan rẹ; emi o bì ọ lulẹ, emi o gbe ọ kalẹ niwaju awọn ọba, ki nwọn ba le wò ọ.
Kà Esek 28
Feti si Esek 28
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Esek 28:13-17
6 Days
Now, more than ever, we are faced with everyone’s life as they want it to be seen, and the comparison to our own lives stirs up envy. You do not want this spirit festering in you, but what about the damage envy causes when it is coming against you from another person? In this reading plan, you will discover how to overcome envy, safeguard your heart, and walk in freedom.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò