Esek 23:18-21
Esek 23:18-21 YBCV
Bayi li o tú idi panṣaga rẹ̀ silẹ, o si tú ihòho rẹ̀ silẹ: nigbana li ọkàn mi ṣi kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn mi ti ṣi kuro lọdọ ẹ̀gbọn rẹ̀. Sibẹsibẹ o mu panṣaga rẹ̀ bi si i ni pipè ọjọ ewe rẹ̀ si iranti, ninu eyi ti o ti ṣe panṣaga ni ilẹ Egipti. Nitoripe o fẹ awọn olufẹ wọn li afẹju, ẹran-ara awọn ti o dabi ẹran-ara kẹtẹkẹtẹ, ati irú awọn ẹni ti o dabi irú ẹṣin. Bayi ni iwọ pe ìwa ifẹkufẹ ìgba ewe rẹ wá si iranti, niti ririn ori ọmú rẹ lati ọwọ́ awọn ara Egipti, fun ọmú ìgba ewe rẹ.

