Eks 8:16-19

Eks 8:16-19 YBCV

OLUWA si wi fun Mose pe, Sọ fun Aaroni pe, Nà ọpá rẹ, ki o si lù ekuru ilẹ, ki o le di iná já gbogbo ilẹ Egipti. Nwọn si ṣe bẹ̃; Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ pẹlu ọpá rẹ̀, o si lù erupẹ ilẹ, iná si wà lara enia, ati lara ẹran; gbogbo ekuru ilẹ li o di iná já gbogbo ilẹ Egipti. Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃ lati mú iná jade wá, ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: bẹ̃ni iná si wà lara enia, ati lara ẹran. Nigbana ni awọn alalupayida wi fun Farao pe, Ika Ọlọrun li eyi: ṣugbọn àiya Farao le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.