Eks 6:6-9

Eks 6:6-9 YBCV

Nitorina wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi li OLUWA, emi o si mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti, emi o si yọ nyin kuro li oko-ẹrú wọn, emi o si fi apa ninà ati idajọ nla da nyin ni ìde: Emi o si gbà nyin ṣe enia fun ara mi, emi o si jẹ́ Ọlọrun fun nyin: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti. Emi o si mú nyin lọ sinu ilẹ na, ti mo ti bura lati fi fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu; emi o si fi i fun nyin ni iní: Emi li OLUWA. Mose si sọ bẹ̃ fun awọn ọmọ Israeli: ṣugbọn nwọn kò gbà ti Mose gbọ́ fun ibinujẹ ọkàn, ati fun ìsin lile.