Ati olukuluku ọkunrin ọlọgbọ́n ninu awọn ti o ṣe iṣẹ agọ́ na, nwọn ṣiṣẹ aṣọ-tita mẹwa; ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, pẹlu awọn kerubu, iṣẹ-ọnà li on fi ṣe wọn. Ina aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ati ibò aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na jẹ́ ìwọn kanna. O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn: ati aṣọ-tita marun keji li o si solù mọ́ ara wọn. O si pa ojóbo aṣọ-alaró li eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù; bẹ̃ gẹgẹ li o ṣe si ìha eti ikangun aṣọ-tita keji nibi isolù keji. Ãdọta ojóbo li o pa lara aṣọ-tita kan, ati ãdọta ojóbo li o si pa li eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji: ojóbo na so aṣọ-tita kini mọ́ keji. O si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, o si fi ikọ́ wọnni fi aṣọ-tita kan kọ́ ekeji: bẹ̃li o si di odidi agọ́. O si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ fun agọ́ na lori ibugbé na: aṣọ-tita mọkanla li o ṣe wọn. Ìna aṣọ-tita kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ibò aṣọ-tita kan si jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla jẹ́ ìwọn kanna. O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn. O si pa ãdọta ojóbo si ìha eti ikangun aṣọ-tita na ni ibi isolù, ati ãdọta ojóbo li o si pa si eti aṣọ-tita ti o so ekeji lù. O si ṣe ãdọta ikọ́ idẹ lati so agọ́ na lù pọ̀, ki o le ṣe ọkan. O si ṣe ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa fun agọ́ na, ati ibori awọ seali lori eyi.
Kà Eks 36
Feti si Eks 36
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Eks 36:8-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò