Eks 35:30-33

Eks 35:30-33 YBCV

Mose si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Wò o, OLUWA ti pè Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah, li orukọ. O si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, li oyé, ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà; Ati lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ, Ati li okuta gbigbẹ́ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà.