NIGBATI awọn enia ri pe, Mose pẹ lati sọkalẹ ti ori òke wá, awọn enia kó ara wọn jọ sọdọ Aaroni, nwọn si wi fun u pe, Dide, dá oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa lọ; bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e. Aaroni si wi fun wọn pe, Ẹ kán oruka wurà ti o wà li eti awọn aya nyin, ati ti awọn ọmọkunrin nyin, ati ti awọn ọmọbinrin nyin, ki ẹ si mú wọn tọ̀ mi wá. Gbogbo awọn enia si kán oruka wurà ti o wà li eti wọn, nwọn si mú wọn tọ̀ Aaroni wá. O si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si fi ohun-ọnà fifin ṣe e, nigbati o si dà a li aworan ẹgbọrọmalu tán: nwọn si wipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ Egipti wá. Nigbati Aaroni si ri i, o tẹ́ pẹpẹ kan niwaju rẹ̀; Aaroni si kede, o si wipe, Ọla li ajọ fun OLUWA.
Kà Eks 32
Feti si Eks 32
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Eks 32:1-5
7 Days
Just like Superman, who can defeat every foe, you as a Christ follower have the supernatural ability to conquer the challenges you face. But the problem for both Superman and you is there’s a kryptonite that steals your strength. This plan will help you uproot spiritual kryptonite from your life, so you can fulfill your God-given potential and embrace a life without limitations.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò