Eks 31:1-11

Eks 31:1-11 YBCV

OLUWA si sọ fun Mose pe, Wò ó, emi ti pè Besaleli li orukọ, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah: Emi si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, ati li oyé, ati ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà. Lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ, Ati li okuta gbigbẹ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà. Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ: Agọ́ ajọ na, ati apoti ẹrí nì, ati itẹ́-ãnu ti o wà lori rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo Agọ́ na. Ati tabili na ati ohun-èlo rẹ̀, ati ọpá-fitila mimọ́ pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari; Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada nì ti on ti ẹsẹ̀ rẹ̀; Ati aṣọ ìsin, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa; Ati oróro itasori, ati turari olõrùn didùn fun ibi mimọ́ nì: gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ ni nwọn o ṣe.