Eks 3:21-22
Eks 3:21-22 YBCV
Emi o si fi ojurere fun awọn enia yi li oju awọn ara Egipti: yio si ṣe, nigbati ẹnyin o lọ, ẹnyin ki yio lọ li ofo: Olukuluku obinrin ni yio si bère ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà, ati aṣọ, lọwọ aladugbo rẹ̀, ati lọwọ ẹniti o nṣe atipo ninu ile rẹ̀: ẹnyin o si fi wọn si ara awọn ọmọkunrin nyin, ati si ara awọn ọmọbinrin nyin: ẹnyin o si kó ẹrù awọn ara Egipti.

