Eks 3:11-13

Eks 3:11-13 YBCV

Mose si wi fun Ọlọrun pe, Tali emi, ti emi o fi tọ̀ Farao lọ, ati ti emi o fi le mú awọn ọmọ Israeli jade lati Egipti wá? O si wipe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ; eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ pe, emi li o rán ọ: nigbati iwọ ba mú awọn enia na lati Egipti jade wá, ẹnyin o sìn Ọlọrun lori oke yi. Mose si wi fun Ọlọrun pe, Kiyesi i, nigbati mo ba dé ọdọ awọn ọmọ Israeli, ti emi o si wi fun wọn pe, Ọlọrun awọn baba nyin li o rán mi si nyin; ti nwọn o si bi mi pe, Orukọ rẹ̀? kili emi o wi fun wọn?