Eks 24:15-18

Eks 24:15-18 YBCV

Mose si gòke lọ sori òke na, awọsanma si bò òke na mọlẹ. Ogo OLUWA si sọkalẹ sori òke Sinai, awọsanma na si bò o mọlẹ ni ijọ́ mẹfa: ni ijọ́ keje o ké si Mose lati ãrin awọsanma wá. Iwò ogo OLUWA dabi iná ajonirun li ori òke na li oju awọn ọmọ Israeli. Mose si lọ sãrin awọsanma na, o sì gùn ori òke na: Mose si wà lori òke li ogoji ọsán ati ogoji oru.