Eks 24:13-18

Eks 24:13-18 YBCV

Mose si dide, ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀: Mose si gòke lọ si oke Ọlọrun. O si wi fun awọn àgba na pe, Ẹ duro dè wa nihinyi, titi awa o fi tun pada tọ̀ nyin wá: si kiyesi i, Aaroni ati Huri mbẹ pẹlu nyin: bi ẹnikan ba li ọ̀ran kan, ki o tọ̀ wọn wá. Mose si gòke lọ sori òke na, awọsanma si bò òke na mọlẹ. Ogo OLUWA si sọkalẹ sori òke Sinai, awọsanma na si bò o mọlẹ ni ijọ́ mẹfa: ni ijọ́ keje o ké si Mose lati ãrin awọsanma wá. Iwò ogo OLUWA dabi iná ajonirun li ori òke na li oju awọn ọmọ Israeli. Mose si lọ sãrin awọsanma na, o sì gùn ori òke na: Mose si wà lori òke li ogoji ọsán ati ogoji oru.