Eks 20:18-21

Eks 20:18-21 YBCV

Gbogbo awọn enia na si ri ãrá na, ati mànamána na, ati ohùn ipè na, nwọn ri oke na nṣe ẽfi: nigbati awọn enia si ri i, nwọn ṣí, nwọn duro li òkere rére. Nwọn si wi fun Mose pe, Iwọ ma bá wa sọ̀rọ̀, awa o si gbọ́: ṣugbọn máṣe jẹ ki Ọlọrun ki o bá wa sọ̀rọ, ki awa ki o má ba kú. Mose si wi fun awọn enia pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitoriti Ọlọrun wá lati dan nyin wò, ati ki ẹ̀ru rẹ̀ ki o le ma wà li oju nyin, ki ẹnyin ki o máṣe ṣẹ̀. Awọn enia si duro li òkere rére, Mose si sunmọ ibi òkunkun ṣiṣu na nibiti Ọlọrun gbé wà.