Eks 18:14-18

Eks 18:14-18 YBCV

Nigbati ana Mose si ri gbogbo eyiti on nṣe fun awọn enia, o ni, Kili eyiti iwọ nṣe fun awọn enia yi? ẽṣe ti iwọ nikan fi dá joko, ti gbogbo enia si duro tì ọ, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ? Mose si wi fun ana rẹ̀ pe, Nitoriti awọn enia ntọ̀ mi wá lati bère lọwọ Ọlọrun ni: Nigbati nwọn ba li ẹjọ́, nwọn a tọ̀ mi wá; emi a si ṣe idajọ larin ẹnikini ati ẹnikeji, emi a si ma mú wọn mọ̀ ìlana Ọlọrun, ati ofin rẹ̀. Ana Mose si wi fun u pe, Eyiti iwọ nṣe nì kò dara. Dajudaju iwọ o dá ara rẹ lagara, ati iwọ, ati awọn enia yi ti o pẹlu rẹ: nitoriti nkan yi wuwo jù fun ọ; iwọ nikan ki yio le ṣe e tikalãrẹ.