Eks 17:10-13

Eks 17:10-13 YBCV

Joṣua si ṣe bi Mose ti wi fun u, o si bá Amaleki jà: ati Mose, Aaroni, on Huri lọ sori oke na. O si ṣe, nigbati Mose ba gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, Israeli a bori: nigbati o ba si rẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ silẹ, Amaleki a bori. Ṣugbọn ọwọ́ kún Mose; nwọn si mú okuta kan, nwọn si fi si abẹ rẹ̀, o si joko lé e; Aaroni ati Huri si mu u li ọwọ́ ró, ọkan li apa kini, ekeji li apa keji; ọwọ́ rẹ̀ si duro gan titi o fi di ìwọ-õrùn. Joṣua si fi oju idà ṣẹgun Amaleki ati awọn enia rẹ̀ tútu.