Eks 15:20-21

Eks 15:20-21 YBCV

Ati Miriamu wolĩ obinrin, arabinrin Aaroni, o mú ìlu li ọwọ́ rẹ̀: gbogbo awọn obinrin si jade tẹle e ti awọn ti ìlu ati ijó. Miriamu si da wọn li ohùn pe, Ẹ kọrin si OLUWA nitoriti o pọ̀ li ogo; ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun.