Eks 15:11-13

Eks 15:11-13 YBCV

Tali o dabi iwọ, OLUWA, ninu awọn alagbara? tali o dabi iwọ, ologo ni mimọ́, ẹlẹru ni iyìn, ti nṣe ohun iyanu? Iwọ nà ọwọ́ ọtún rẹ, ilẹ gbe wọn mì. Ninu ãnu rẹ ni iwọ fi ṣe amọ̀na awọn enia na ti iwọ ti rapada: iwọ si nfi agbara rẹ tọ́ wọn lọ si ibujoko mimọ́ rẹ.