Ninu eyiti ọba fi aṣẹ fun gbogbo awọn Ju, ti o wà ni ilu gbogbo, lati kó ara wọn jọ, ati lati duro gbà ẹmi ara wọn là, lati parun, lati pa, ati lati mu ki gbogbo agbara awọn enia, ati ìgberiko na, ti o ba fẹ kọlu wọn, pẹlu awọn ọmọ wẹwẹ ati awọn obinrin ki o ṣegbe; ki nwọn ki o si kó ìni wọn fun ara wọn, Li ọjọ kanṣoṣo ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, li ọjọ kẹtala, oṣù kejila ti iṣe oṣù Adari. Ọ̀ran inu iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo ìgberiko lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki awọn Ju ki o le mura de ọjọ na, lati gbẹsan ara wọn lara awọn ọta wọn. Bẹ̃ni awọn ojiṣẹ́ ti nwọn gun ẹṣin yiyara ati ibãka jade lọ, nitori aṣẹ ọba, nwọn yara, nwọn sare. A si pa aṣẹ yi ni Ṣuṣani ãfin.
Kà Est 8
Feti si Est 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Est 8:11-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò