Est 7:5-7

Est 7:5-7 YBCV

Nigbana ni Ahaswerusi ọba dahùn, o si wi fun Esteri ayaba pe, Tali oluwa rẹ̀ na, nibo li o si wà, ti o jẹ gbe e le ọkàn rẹ̀ lati ṣe bẹ̃? Esteri si wi pe, ọlọtẹ enia ati ọta na ni Hamani, ẹni buburu yi. Nigbana ni ẹ̀ru ba Hamani niwaju ọba ati ayaba. Ọba si dide ni ibinu rẹ̀ kuro ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini, o bọ́ si àgbala ãfin. Hamani si dide duro lati tọrọ ẹmi rẹ̀ lọwọ Esteri ayaba; nitori o ti ri pe ọba ti pinnu ibi si on.