Bẹ̃ni ọba ati Hamani wá iba Esteri ayaba jẹ àse. Ọba si tun wi fun Esteri ni ijọ keji ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini pe, kini ẹbẹ rẹ, Esteri ayaba? a o si fi fun ọ: ki si ni ibère rẹ? a o si ṣe e, ani lọ ide idaji ijọba. Nigbana ni Esteri ayaba dahùn wi pe, bi mo ba ri ore-ọfẹ loju rẹ ọba, bi o ba si wù ọba, mo bẹbẹ ki a fi ẹmi mi bùn mi nipa ẹbẹ mi, ati awọn enia mi nipa ibère mi. Nitori a ti tà wa, emi ati awọn enia mi, lati run wa, lati pa wa, ki a le parun. Ṣugbọn bi o ṣe pe, a ti tà wa fun ẹrúkunrin, ati ẹrúbirin ni, emi iba pa ẹnu mi mọ́, bi o tilẹ jẹ pe ọta na kò le di ofò ọba.
Kà Est 7
Feti si Est 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Est 7:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò